Fun oriire ni aye yi ati ni orun, oranyan ni fun Musulumi ki o mo wipe Al-kurani ati Sunna ni ohun yoo maa seri si fun gbogbo oro esin re. Eleyi si ni isesi awon eni isiwaju lati ori awon Saabe Ojise Olohun ati awon ti won tele ilana won. Eyi ni o je ki won di eni iyonu ni iwaju Olohun, ti won si jinna si ona anu ati gbogbo aburu ni oniran iran.